Ìyàwó àti Bàbá Toluwanisings, ọ̀rẹ́ àti alájọṣe lọ ilééṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo torí aáwọ̀ ààrin wọn, kókó ohun tí wọn ṣe níbẹ̀ rèé

Awọn ẹbi ti Toluwanisings wọ asọ ankara alawọ pọpu to jẹ alaranbara, wn n fi ọwọ siwe adehun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 13

Gbogbo ariyanjiyan, ikun sinu to wa laarin iyawo gbajugbaja Olorin ẹmi Olayemi Bayonle Bolaji, ẹniti ti ọpọ eeyan mọ si Toluwanisings ati awọn ẹbi ọkọ rẹ, lo ti lọ odo lọ sinmi bayii.

Eyi lo waye nitori igbesẹ ipẹtu si aawọ ti kọmisana ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Abimbola Ayodeji gbe lati pẹtu si aawọ to wa ninu idile naa lẹyin iku oloogbe.

‎Atẹjade ti alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fi lede ṣalaye pe kọmisana ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lo dasi ariyanjiyan to suyọ lori ibi ti wọn yoo sin olorin ẹmi naa si.

Saaju ni ọrọ yii ti da ariyanjiyan silẹ laarin idile ologbe olorin ẹmi naa ati iyawo rẹ.

‎Ọrọ naa si tun lo se okunfa ẹsun ibanilorukọjẹ, iditẹmọni ati tita abawọn si asọ ẹni eyi to n lọ lori ayelujara laarin ẹbi ati iyawo oloogbe eyi to seese ko da aawọ silẹ laarin igun mejeeji.

Obinrin kan ro iro ati buba ankara alawọ pọpu, ko we gele, o mu gege dani sori iwe to wa lori tabili

Se agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, idi ree ti Kọmisana ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo se lo aṣẹ to wa ninu abala ìkẹrin ofin ile iṣẹ ọlọpaa, to wa lati dena ki ọrọ to nja rain-rain naa, ma ba fẹ loju ju bose yẹ lo, ki o si ni iyanju ni itubi nubi.

‎Abimbola Ayodeji wa pe awọn igun ti ọrọ yii kan lati yọju si olu ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo to wa ni agbegbe Eleiyele nilu Ibadan.

‎Tẹẹ ba gbagbe, ọlọkan-o-jọkan ariwo lo gba ori ayelujara kan lati bii ọsẹ meji sẹyin bi iyawo ati ẹbi oloogbe Toluwanisings se n sọrọ si ara wọn.

‎‎Awon ẹbi Toluwanisings n sọ nigba naa pe awọn fẹ ki wọn sin in sile rẹ tabi ilu Ikirun ti i ṣe ilu baba rẹ.

Amọ iroyin kan ni iyawo oloogbe sọ pe ki wọn maṣe sin ọkọ oun sinu ile rẹ, pe ki wọn lọ sin in si itẹ oku igboro ni.

‎Eyi lo fa ọlọkan-o-jọkan ọrọ lori iyawo to bimọ meji naa, ti awọn kan n sọ pe o fẹ jogun ọkọ ni ko ṣe fẹ ki wọn si Toluwanisings sile to kọ.

Baba Toluwanisings wọ ankara toketilẹ alawọpọpu ati fila rẹ, o mu gege dani sori iwe to wa lori tabili

‎ Ki ni wọn fẹnu ko le lori nibi ipade adehun naa?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nibi ipade alafia naa to waye ni Ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹta osu Kọkanla ọdun 2026 ni igun mejeeji ti fọwọ si iwe adehun niwaju Kọmisana Ọlọpaa pe alaafia yoo maa jọba laarin wọn.

Awọn to peju pesẹ sibi Ipade alafia ọhun, ti wọn si fọwọ si iwe adehun naa ni iyawo oloogbe, Olayemi Elizabeth Danilola, Baba Oloogbe, Muniru Olayemi ati awọn ọrẹ pẹlu alabaṣiṣẹpọ Toluwanisings.

Lara wọn ni Oyindamola Esther, Babadunni Gbolabọ ati Lawal Ademola Rafiu.

Gbogbo awọn eeyan naa si lo fọwọ si iwe adehun naa pe lati akoko yii lọ, awọn ko ni gbe igbesẹ to le tako adehun alaafia ti wọn fọwọsi.

Wọn ni awọn ko ni maa dahun si ara awọn loju aye lori ayelujara mọ tabi se ifọrọwerọ ati ijiroro to le da omi adehun alaafia ti wọn fọwọsi ru.

‎Atejade naa fofin de ki idile naa ba awọn akọroyin sọrọ tabi ṣe ifọrọwerọ loju ikanni ayelujara kankan, eleyii to le mu ki ikun sinu ko wa ninu ẹbi naa, eleyii ti igun mejeeji si fọwọsi.

Bakan naa ni wọn fẹnuko pe awọn yoo ba awọn ololufẹ awọn sọrọ lati dẹkun sisọ ọrọ tabi se onigbọwọ eto tabi maa pin awọn iwe to le mu aigbọraẹniye wa, eyi to le ba adehun alaafia ti wọn fọwọsi jẹ.

Awọn ẹbi Toluwanisings ati ọlọpaa joko yika tabili lati tọwọ bọ iwe adehun lati jẹ ki alaafia jọba

Ẹ bọwọ fun adehun alaafia pẹlu ọlọpaa, ẹnikẹni to ba yẹ adehun alaafia naa huwa ọdaran, a si fi ọwọ ofin mu igbesẹ naa - Ọlọpaa

Kọmisana ọlọpaa wa sekilọ fun igun mejeeji pe ki wọn bọwọ fun adehun alaafia naa, to fi mọ awọn alatilẹyin wọn.

‎O tun sekilọ fawọn araalu pe ẹnikẹni ko gbọdọ lo anfaani iku oloogbe naa lati da rugudu silẹ nipa fifi ẹsun kan ara wọn tabi gunle awọn iwa to le da omi alaafia ilu ru.

Ayodeji wa fi ewe ọmọ mọ awọn eeyan naa leti pe ẹnikẹni to ba tapa si adehun alaafia naa ni Ọlọpaa yoo gbe, ti yoo si ba wọn se ẹjọ.

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo wa ke sawọn araalu, awọn agbetojade lori ayelujara, awọn akọroyin ati araalu lapapọ lati sọrase, ki wọn si bọwọ fun iwe adehun ti awọn eeyan naa fọwọ si.

Kọmisana ọlọpaa wa rọ awọn igun ti ọrọ naa kan lati bọwọ fun adehun alaafia naa nitori bi eyikeyi wọn ba yẹ adehun naa, o ja si iwa ọdaran, ti wọn yoo si fin ọwọ ofin mu igbesẹ naa.

Àkọlé fídíò, "Inú ebi la wà ní Igbokoda láti ìgbà tí bàálù ti já, omi ẹ̀rọ kò ṣe fà, à ń ra omi mu ni, a kò sì le pa ẹja"

Ìyàwó àti ẹbí Toluwanisings ti fẹnu kò lórí ibi tí wọn yóò sin okú rẹ̀ sí

Iyawo Oloogbe Toluwanisings; Damilola Olayemi ati Oloogbe Bayonile Olayemi (Toluwanisings)

Lẹyin gbogbo awuyewuye to ti waye nipa ibi ti wọn yoo sin oku Oloogbe Bayonile Olayemi tawọn eeyan mọ si Toluwanisings, si, iyawo ti akọrin naa fi silẹ atawọn ẹbi rẹ ti fẹnuko lati sin oku rẹ siluu Ibadan.

Ọjọ Aiku ana ti i ṣe ọjọ kin-in-ni oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii ni Damilola Olayemi to jẹ iyawo Oloogbe Toluwanisings atawọn idile ọkọ rẹ, fẹnuko lati sinku Toluwanisings si ile rẹ niluu Ibadan.

Ta lo sọ eyi di mimọ?

Akọrin ẹmi kan, Lanre Alewilese to jẹ alajọṣe pẹlu Oloogbe Toluwanisings lo kede ọrọ yii ninu fidio kan to fi soju opo Instagram rẹ.

Alewilese sọ pe gbogbo ohun to fa ariyanjiyan lori isinku naa ni awọn eeyan naa ti yanju bayii.

O ni wón ti fẹnuko lati sin Toluwanisings sile rẹ to kọ siluu Ibadan to n gbe nigba aye rẹ.

Gẹgẹ bi Alewilese ṣe wi:

"Awuyewuye to waye laaarin awọn ẹbi Baba Toluwanisings ati iyawo rẹ ti yanju. Aigbọra ẹni ye lasan ni ohun to ṣẹlẹ.

"Awọn mejeeji ti gba lati sin Toluwanising si ile rẹ."

"Ẹ jọwọ, ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ jẹ ki iyawo Toluwanisings sinmi bayii ti ẹnu ti ko lori ibi ti wọn maa sin ọkọ rẹ si"

Bi akọrin ẹmi to ni oun mọ Oloogbe naa deledele ṣe sọrọ yii naa lo tun bẹ awọn eeyan lati yee ko idaamu ba iyawo Toluwanisings.

Alewilese bẹbẹ ninu fidio naa pe:

"Ẹ jọọ, ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ jẹ ki alaafia jọba.

"To ba jẹ loootọ lẹ fẹran akọrin yii, ẹ jẹ ki iyawo rẹ sinmi bayii ti wọn ti fẹnuko lati sinku sile rẹ.

"Ẹ jọọ nitori Ọlọrun, ẹ jẹ ki alaafia jọba. Damilola ṣi kere si ohun to n la kọja. Mo sunmọ Oloogbe gan-an, iyawo rẹ yii ko eeyan mọra. Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ọkọ rẹ lo le jéri si eyi."

Bẹẹ ni Lanre Alewilese wi.

Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju

Tẹ o ba gbagbe, ọlọkan-o-jọkan ariwo lo gba ori ayelujara kan lati bii ọsẹ meji sẹyin.

Awon ẹbi Toluwanisings n sọ nigba naa pe awọn fẹ ki wọn sin in sile rẹ tabi ilu Ikirun ti I ṣe ilu baba rẹ.

Iroyin to tẹle eyi si ni pe wọn ni iyawo oloogbe sọ pe ki wọn ma ṣe sin in sile rẹ, pe ki wọn lọ sin in si itẹ oku igboro ni.

Eyi lo fa ọlọkan-o-jọkan ọrọ lori iyawo to bimọ meji naa, ti awọn kan n sọ pe o fẹ jogun ọkọ ni ko ṣe fẹ ki wọn si Toluwanisings sile to kọ.

Bayii ṣaa ti ẹnu ti ko pe ki won si olorin naa sile rẹ, igbagbọ ọpọ eeyan ni pe ohun to n rùn lori isinku Toluwanisings yoo tan nilẹ.

BBC News Yoruba yoo mu ọjọ isinku naa wa ati bo ba ṣe n lọ fun yin.

Ẹ kò lè bá Toluwanisings nídìí ìbàjẹ́, lọ wá iṣẹ́ ṣe tí o ò bá níṣẹ́- Laolu Gbenjo

Toluwanisings nigba to wa laye, ati iyawo rẹ

Ọpọ ara, ọrẹ ati ojulumọ lo wa nibi eto idagbere to waye nji alẹ ana ti wọn pe ni : Night of Tribute .

Eyi ni wọn fi sami aṣalẹ idagbere fun Olayemi Bayonle ti gbogbo eeyan mọ si Toluwanisings, nibẹ ni ọpọ olorin ẹmi bii Yinka Alaṣeyọri, Bidem Olaoba, Laolu Gbenjo ati awọn mii wa.

Laarin isin aṣalẹ yii ni Laolu Gbnjo ti sọ fun gbogbo ero pe o to gẹ lori ẹjo ti awọn eeyan n ro lori iṣẹlẹ iku Toluwanisings ati ẹjọkejọ lori idile ẹ.

Laolu Gbnejo sọrọ nipa oloogbe si awọn eeyan pe:-

Ẹ kò lè rí Toluwanisings láàárín àwọn aláìníṣẹ́. Ó ní ọkàn rere si gbogbo èèyàn ni.

Ó sin Ọlọrun tọkàntọkàn.

Ẹ má ṣe sọ Toluwani di Mohbad. Ẹ dẹ́kun gbogbovọ̀rọ wèrè orí Tiktok àti Instagram. Bí ẹ kò bá níṣẹ́, ẹ lọ wá iṣẹ́ ṣe

Ọkọ mi, má gbágbé emi ati awọn ọmọ rẹ- Elizabeth aya Toluwanisings

Orisirisi awuyewuye lo ti n jade lẹnu awọn ẹbi, ara ati ojulumọ lori eto isinku gbajumọ olorin ẹmi nni, Bayonle Olayemi ti ọpọ mọ si Toluwanisings.

Bi awọn kan ṣe n beere pe ki lo ṣi n da eto isinku naa duro, ni awọn miran n sọ pe aigbọra-ẹni-ye ni.

Awọn kan sọ pe irọ ni wi pe Elizabeth Olayemi, aya Toluwanisings sọ bẹẹ.

Bakan naa ni awọn miran n sọ pe Baba ọkọ rẹ, Alagba Muniru Olayemi ko le purọ mọ iyawo ọmọ rẹ rara.

Awọn miran ṣalaye lori idi ti Elizabeth fi le sọ bẹẹ pe boya nitori ibanujẹ ọjọ ni, tabi nitori pe ki ẹru ma maa ba a lẹyin isinku.

Bẹẹ naa ni ero awọn kan ja si pe ṣe bi Toluwanisings lo ṣe wahala lati kọ ile rẹ, ko sun si ile to kọ funra rẹ.

Bayonile Olayemi, akọrin ẹmi to doloogbe

Ṣé lóòótọ́ ni ìyàwó Toluwanisings sọ pé kí wọ́n má sin òkú ọkọ rẹ̀ sílé wọn?

Lati bi ọjọ meloo sẹyin ni awuyewuye tun ti dide lori ọrọ ibi ti wọn yoo sinku gbajugbaja onkọrin igbagbọ nni, Ọlayemi Bolaji Bayonile tọpọ mọ si Toluwanisings si.

Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ọrọ iku onkọrin naa ṣi n jẹ kayeefi fawọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye.

Ṣugbọn ni bayii, bi wọn ṣe sọ pe iyawo oloogbe naa ṣe n sọ pe oun ko fẹ ki wọn sinku ọkọ oun sinu ile to kọ, bẹẹ ni baba rẹ n sọ pe inu ile naa loun fẹ ki wọn sinku ọmọ oun si.

Kí ló tún ń fa awuyewuye lórí ìsìnkú Toluwanisings? Ohun tí a mọ̀ rèé

Fọnran ifọrọwerọ ti baba to bi Toluwanisings, Muniru Adekunle Olayemi ṣe laipẹ yii, to si n ja rainrain lori ayelujara, lo ti ṣalaye irin ajo ọmọ rẹ.

Baba naa sọ pe nnkan to le dun mọ oun ninu ju ni ki sinku Bayonle Olayemi sinu ile rẹ to kọ.

"Inu oṣu Keje, ọdun 1992 ni a bi ọmọ mi, Sodiq Bayonle Olayemi ni mo sọ orukọ rẹ lọjọ ti a sọ ọ lorukọ," baba naa fidi rẹ mulẹ.

"Akọrin ẹmi ni ninu ṣọọsi to n lọ, ibẹ lo si ti bẹrẹ iṣẹ orin. Ibẹ lo ti ri akọrin ẹgbẹ rẹ, to fẹ ni iyawo. Asiko igba to bẹrẹ sii kọrin ẹmi lo fi yi orukọ rẹ pada si Toluwani.

"Igba to di Kristiẹẹni, inu mi dun, nitori pe Kristiẹẹni ati Musulumi lo wa ninu idile wa, kii ṣe pe o n ṣe abọriṣa, Ọlọrun kan naa la n sin," o fidi rẹ mulẹ.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe oloogbe naa lo beere lati mọ awọn aburo rẹ ti obinrin miran bi foun, to si latigba naa ni wọn ti n ṣe wọlewọde.

"Ipo keji ni Toluwanisings wa ninu awọn ọmọ mi. Ọjọ kan lo pe mi pe ṣe oun ko ni aburo ni, mo sọ pe o ni. Loju ẹsẹ lo ti gba ẹrọ ibanisọrọ rẹ, ti wọn fi bẹrẹ sii sọrọ,"

Bàbá náà sọ ẹ̀dun ọkàn rẹ̀

Ọgbẹni Muniru Olayemi sọ pe nnkan kan ṣoṣo to le dun mọ oun ninu julọ, ni wọn sinku ọmọ oun sinu ile to jiṣẹ-jiya kọ, ko too jade laye.

O ni yoo si maa wa ni iranti awọn mọlẹbi, ni gbogbo igba ti wọn ba n de inu ile naa.

Siwaju sii lo ni gbara toun gbọ nipa iku ọmọ oun, loun ti ṣabẹwo si iyawo rẹ, to si loun sọ nnkan toun fẹ fun un, ṣugbọn to ni iyawo naa sọ pe ko le ṣee ṣe.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe, bi wọn ko ba le sinku ọmọ oun sinu ile to kọ, ki wọn gbe e lọ si ibi ti wọn sinku mama rẹ si lọdun mẹrinlelọgbọn sẹyin.

"Mi o fẹ ki wọn gbe oku ẹ lọ si itẹ tabi ṣọọṣi kan, ki wọn sin in sinu ile ẹ, lo le dun mọ emi ninu ju," Baba Toluwanisings sọ ẹdun ọkan rẹ.

O tẹsiwaju pe, "Nigba to kọ ile, inu ile rẹ ni ki wọn sin in si. Wọn si n fa a, o ni oun ko le maa fi ojoojumọ maa wo saare ọkọ oun. Ṣe ti wọn ba wa gbe e lọ si ṣọọṣi, ṣe ibẹ lo ti fẹ maa lọ gbadura fun un ni?

"To ba ri bẹẹ, ti ẹ ba mọ pe ẹ ko le sin sinu ile to kọ, ẹ gbe wa si Ikirun, ki wọn wa sin sẹgbẹ iya ẹ," Baba naa ṣalaye.