Ọ̀rọ̀ oyè Awujale tún gba ọ̀nà míì yọ, bí igbákejì alága ìdílé Funsegbuwa ṣe wọ́ àwọn èèyàn tó ya kúrò nínú ìdílé lọ sílé ẹjọ́, bèèrè N10bn

Oríṣun àwòrán, Others
Ifanfa to n waye ninu idile Fusengbuwa, Ijebu Ode lori oye Awujale ilẹ Ijebu tun ti gba ọna mii yọ bi oloye Fassy Adetokunboh Yusuf, ẹni to jẹ igbakeji alaga idile naa ṣe wọ awọn eeyan mọkanla kan ti wọn fẹsun kan pe won ya kuro ninu idile naa l.o sile ile ẹjọ.
Ni ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ ni Oloye Fassy wọ awọn eeyan naa lọ siwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Ogun fun ẹsun ibanilorukọjẹ to si n beere fun owo itanran biliọnu mẹwaa naira gẹgẹ bi owo itanran.
Oloye Fusengbuwa fẹsun kan niṣe ni awọn eeyan naa ba oun lorukọ ninu atẹjade kan ti wọn gbe jade labẹ igbimọ kan ti wọn lo n ṣe iwadii lori ohun to jẹ ootọ ninu idile Fusengbuwa.
Oloye Fassy pe ẹjọ́ lori ẹsun ti wọn fi kan-an pe o n gba owo abẹtẹlẹ, fi owo tan awọn oludije ati lilọwọ ninu yiyi iwe
Awọn ti Oloye Fusengbuwa naa pe lẹjọ ni Pa Olusegun Olusoga, Ridwan Odunrye, Muyiwa Adeleye, Alhaji Taiwo Ajumo, Sikiru Adegunwa, Kehinde Lawal, Logunleko Oludare, Ọmọọba Abdul Onalaja, Ashiru Mufutau, Ọmọọba Osiyemi Johnson ati Ọmọọba Adeleke Adeyemi.
Fassy ninu ẹjọ to pe lo ti n pe agbejade awọn eeyan naa nija paapaa ẹsun ti wọn fi kan-an pe o n gba owo abẹtẹlẹ, fi owo tan awọn oludije ati lilọwọ ninu yiyi iwe.
O ni ki ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe irọ patapata ni gbogbo ohun tawọn eeyan naa kọ sinu iwe naa, to jẹ ohun to le ba oun lorukọjẹ, to si le ta epo si aala oun.
Bakan naa lo tun n fẹsun kan agbekalẹ igbimọ ọhun jẹ ko ba ofin mu, bo ṣe fẹsun kan pe wọn ko tẹle ilana ofin ati pe igbimọ naa ko laṣẹ lati ṣe iwadii oun tabi fẹnuko lori awọn ohun to le bao un lorukọjẹ tabi ki oun lo jẹjọ niwaju igbimọ ile awọn naa.
O n beere pe ki ile ẹjọ wọ awọn nnkan ti oun ka kalẹ agbejade awọn eeyan naa, ki wọn dajọ pe igbimọ naa ko lẹtọọ labẹ ofin lati ṣe iwadii ti wọn gbe jade, ki ile ẹjọ si kede rẹ ni ofutufẹtẹ.
O fi kun pe ki ile ẹjọ gba owo itanran biliọnu mẹwaa naira gẹge bi owo itanran fun oun lori ibanilorukọjẹ ti agbejade naa ṣe fun oun.
Bakan naa lo tun n beere fun miliọnu marun-un naira gẹgẹ bi owo ti igbesẹ naa gba oun ati pe ki ile ẹjọ paṣẹ fawọn eeyan naa lati ma kọ ohunkohun nipa oun mọ paapaa awọn nnkan to le bao un lorukọ jẹ.
Oloye Fassy tun tẹsiwaju lati beere lọwọ ile ẹjọ pe ki wọn sọ fun awọn eeyan lati ko awọn nnkan ti wọn kọ nipa oun jẹ, ki wọn si tun tọrọ aforiji lọwọ oun, ki wọn si tẹ aforiji naa jade ninu awọn iwe iroyin olojoojumọ Naijiria, ki wọn gbe jade lori ikanni ayelujara atawọn ilana mii.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ipenilẹjọ yii lo n waye bi aigbọraẹniye to n waye ninu ẹbi idile oye Fusengbuwa lori awọn adari idile naa atawọn ọrọ to rọ mọ yiyan Awujale ilẹ Ijebu.
Idile Fusengbuwa ni o kan lati yan ọmọ oye to maa jẹ Awujalẹ ilẹ Ijebu leyin ti ipapoda Awujalẹ to gbesẹ, Oba Sikiru Kayode Adetona to darapọ mọ awọn babanla n rẹ lọjọ Kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2025.
Ṣaaju n idile naa ti fi orukọ awọn ọmọ ranṣẹ sawọn afọbajẹ ilu Ijebu amọ ti idaduro tib a igbesẹ naa lati odun to kọja eyi to mu kawọn idile naa wọ ijọba ipinlẹ Ogun atawọn afọbajẹ mẹsan-an lọ sile ejọ lori ọrọ oye naa.
Ohun ti awọn idile naa n fẹ ninu ẹjọ ti wọn pe ni pe ki awọn afọbajẹ jokoo laaarin ọjọ meje ti ile ẹjọ bag be idajọ rẹ kalẹ ki wọn si pari gbogbo igbesẹ yiyan Awujale tuntun.
Bakan naa ni wọn pe ijọba ipinlẹ Ogun lẹjọ lori wọn n da si ọrọ oye naa eyi ti wọn ni awọn ko fẹ rara.
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, idajọ ko i tii waye lori ẹjọ ti idile Fusengbuwa pe awọn afọbaje ati ijọba ipinlẹ Ogun.



























