Putin ṣe tán sáà kẹrin gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Russia

Puttin
Àkọlé àwòrán, Puttin ti wa ni ipo olori ijọba Russia lati ọdun 1999
Published

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Russia Vladimir Putin l'agbọ́ pe wọn yóò búra wọle fún sí ipò gẹgẹ bí Ààrẹ fún ìgbà kẹrin lẹyìn tí ó pegedé nínú ibo tó wáyé lósù kẹta.

Fún nkan bíi ọdún méjìdínlógún lo tí n se ìjọba yala nípo Ààrẹ tàbí olootu ìjọba.

Èyí mú kí àwọn alátakò se àpèjúwe rẹ gẹgẹ bí apàṣẹ wàá.

ọlọpaa ati awọn oluwọde
Àkọlé àwòrán, Ikolu awọn ọlọpaa kogberegbe ati àwọn tó n wọde waye lawọn ilu kan ni Russia

Nílu Moscow àti awọn ìlú míràn ni Russia àwọn ìkọ ọlọpaa kogberegbe kojú àwọn tó n wọde .

Ìpayà wà wí pé dàrú dàpọ̀ le wáyé lọ́jọ́ ajé tí wọ́n yóò búra fún un.

Ìbúrawolé ọ̀ún ní ile ìjọba Kremlin la gbọ́ wí pé ó lè má lárinrin bí èyí tó wáyé ní ọdún 2012.