Inú mi kò dùn nígbà tí Taiwo mi ṣe ìgbéyàwó torí ó dà bí ẹni pé wọ́n gba ìyàwó mi ni - Kehinde Afolabi

Àkọlé fídíò, Inú mi kò dùn nígbà tí Taiwo mi ṣe ìgbéyàwó torí ó dà bí ẹni pé wọ́n gba ìyàwó mi ni - Kehinde Afolabi
Inú mi kò dùn nígbà tí Taiwo mi ṣe ìgbéyàwó torí ó dà bí ẹni pé wọ́n gba ìyàwó mi ni - Kehinde Afolabi
Published

Awọn ibeji kan, Tayelolu ọmọ Afolabi ati Kehinde Gabriel Afolabi, ree ti ina ifẹ to wa laarin si n jo lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti onikaluku wọn ti ni idile tireẹ.

Arabinrin Taiwo sọ fun BBC News Yoruba wi pe ''ilakọja wa kii ṣe kekere nitori ọdun 1970 ni baba wa ku.

Iku yajo yajo ni baba wa ku tori o ba wa lojiji.

Iku baba wa lo jẹ ki emi ati ekeji mi di ẹni ti ko le lọ ile iwe mọ.

Bayii ni awa mejeeji ṣe lọ kọ iṣẹ, koda,ọjọ kan naa ni a gba iyọnda lẹnu iṣẹ.

Iṣẹ aranṣọ ni emi kọ nigba ti Kehinde mi kọ iṣẹ fọto yiya.''