You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Irọ́ ni Portable n pa wí pé mo gé òun jẹ, ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò ìjà wa rèé - Charles Okocha
Gbajugbaja oṣere nni, Charles Okocha ti sọ pe irọ to jinna si otitọ ni gbajumọ olorin takasufee nni, Habeeb Okikiola tọpọ mọ si Portable pa wi pe oun ge e ẹ lasiko ti awọn jọ jijakadi.
Okocha sọ pe anasare loun lu Portable naa, to si jẹ ko salọ foun lasiko ija naa.
Gbajumọ naa jẹ ko di mimọ pe kii ṣe pe awọn kan deedee ṣagbekalẹ ija ti awọn ja laipẹ yii.
O ni Portable lo n sọ kaakiri pe oun lu oun nibi ija ti awọn ja lọdun 2023, to si fi n gberaga soun kaakiri.
Idi ree to loun tun fi pe Portable nija lati ja ija miran lọdun 2026.
Okocha sọ pe oun mura lọ ba Portable lati ja ija ti awọn ja laipẹ yii ni, to fi jẹ koun lu nilukulu.
Irọ́ ni Portable pa wí pé mo gé òun jẹ
Ọkunrin naa jẹ ko di mimọ pe oun ko ge Portable jẹ, gẹgẹ bo ṣe n sọ kaakiri, o sọ pe alubami toun luu, lo jẹ ko na papa bora.
"Portable n purọ, o ni mo ge oun jẹ, irọ lo n pa a, mi o ge jẹ ẹ, anasare ni mo fun un jẹ," Okocha sọ bẹẹ.
"Ẹṣẹ ti emi ati Portable ja, ẹṣẹ yẹn wapa, anasare ni mo lu Portable, o si sare.
"Ṣebi oun lo maa n sọ fawọn eeyan pe oun lu mi ni ọdun 2023.
"O maa n sọ fun gbogbo eeyan pe oun fi ẹṣẹ ba mi jẹ. Mo wa fi silẹ, mo sọ pe, o dara, iwọ ti o fi ẹṣẹ ba mi jẹ ni 2023, ki lo wa ṣẹlẹ niisinyi."
Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìja 2023 àti 2026
Okocha sọ pe iyatọ wa laaarin ija toun pẹlu Portable ja lọdun 2023 ati 2026.
"A gun ori papa ija, mo lu nilukulu, mo lu u pa. Ẹ lọ beere, mo luu pa. Mo fi ẹṣẹ ba a jẹ. Oun naa mọ, o wa sare.
"Nnkan to ṣẹlẹ ni pe, nigba ti a ja ni 2023, ọtọ ni ija yẹn, ọtọ si ni ija 2026.
"Portable naa ti rii pe baba yii ti gbera gan-an, o si salọ. Nigba to salọ, o wa sọ fawọn eeyan pe alubarika lo ju.
"Oun naa mọ nnkan ti oju oun ri, nnkan to ṣẹlẹ niyẹn."