Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ TUC tako àdéhùn N70,000 náírà tí ìjọba àpapọ̀ ṣèlérí, wọ́n bèèrè fún àfikún owó oṣù tuntun

Awọn oṣiṣẹ lẹgbẹ TUC
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Kii ṣe ahesọ tabi iroyin tuntun wi pe ijọba apapọ ti buwọlu ẹgbẹrun lọna aadọrin naira gẹgẹ bi owo iranwọ fawọn oṣiṣẹ ijọba kaakiri Naijiria.

Agbekalẹ yii lo waye nibi ipade ti awọn aṣoju ijọba apapọ ṣe pẹlu awọn olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, ẹka ti NLC.

Atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Festus Osifo, ati akọwe agba rẹ, N.A Toro fi sita l'Ọjọru lo fidi rẹ mulẹ, lẹyin ipade ti igbimọ amuṣẹṣe wọn ṣe niluu Abuja lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa.

Lẹyin ikede naa, ẹka ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti Trade Union Congress, TUC ti sọ pe awọn ko faramọ agbekalẹ nipa owo ọkọ ẹgbẹrun lọna aadọrin naa.

TUC sọ pe kaka ki ijọba ṣe iranwọ fawọn oṣiṣẹ nipa fifun wọn lowo naa, wọn ni ṣe lo yẹ ki ijọba apapọ fa owo oṣu awọn oṣiṣẹ lọ soke.

Awọn alakoso ẹgbẹ naa sọ pe kii ṣe igbesẹ to le dena adojukọ awọn oṣiṣẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọrin naira gẹgẹ bi owo ọkọ wiwọ, bi ko ṣe pe ki wọn wa iyanju si.

Yatọ si eyi, TUC fẹsun kan ijọba apapọ lori bi wọn ṣe ni ko mu ileri rẹ to ṣe fun wọn lọdun 2023 nipa ọrọ owo oṣu ṣẹ, ti wọn si ni ijọba apapọ gbagbe ajọsọ oṣu meje lori afikun owo oṣu, labẹ eto ti wọn pe ni Consolidated Health Salary Structure fawọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn wa labẹ JOHESU.

Ninu atẹjade naa, TUC sọ pe awọn ti kọwe sijọba apapọ nipasẹ akọwe agba, nibi ti wọn ti n beere fun agbeyẹwo lori owo oṣu tuntun, ni ibamu pẹlu bi owo nnkan ṣe lọ soke.

Awọn alakoso naa sọ pe ijọba ko nilo lati duro de ijiroro lori owo oṣu apapọ, ko to di pe wọn ṣe afikun lori owo oṣu awọn oṣiṣẹ, nitori pe ko si ofin kankan to de iye ti awọn agbanisiṣẹ le san fawọn oṣiṣẹ wọn.

"O yẹ ki ijọba apapọ ṣe agbeyẹwo afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ. Eleyi lo jẹ pe ijọba ko nilo lati jokoo ijiroro tabi ajọsọ lori fifi kun owo oṣu awọn oṣiṣẹ, nitori pe ko si ofin to de iye owo ti oṣiṣẹ le gba mọ," atẹjade naa sọ bẹẹ.

Ẹgbẹ naa wa sọ pe awọn n fẹ afikun owo oṣu oṣiṣẹ lati ẹgbẹrun lọna aadọrin to wa, lọ si ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira.

Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC tọ́wọ bọ̀wé àdéhùn, buwọ́lu N70,000 náírà gẹ́gẹ́ bí owó ọkọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́
Aarẹ Bola Tinubu ati alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC, Joe Ajaero

Lojuna lati mu igbe aye idẹrun ba awọn oṣiṣẹ ijọba kaakiri ilẹ Naijiria, ijọba apapọ ti tọwọ bọwe adehun tuntun pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC.

Bo tilẹ jẹ pe oniruuru ijiroro lo waye laaarin awọn aṣoju ijọba ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, sibẹ, gbogbo wọn lo panupọ lati fẹnuko lori adehun tuntun.

Nibi ipade ti awọn alakoso NLC ati ijọba apapọ ṣe lọjọ kejilelogun, ati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii, ni wọn ti buwọlu ẹgbẹrun lọna aadọrin naira gẹgẹ bi owo iranwọ ọkọ wiwọ fun awọn oṣiṣẹ.

Ajọ NLC lo sọrọ nipa adojukọ awọn oṣiṣẹ pẹlu bi owo ọja ṣe lọ soke, owo oṣu tuntun awọn oṣiṣẹ, owo epo to lọ soke, to fi mọ igbayegbadun awọn oṣiṣẹ.

Ọmọwe Muhammad Maigari Dingyadi, to jẹ minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ lo buwọ lu iwe adehun naa pẹlu NLC lorukọ ijọba apapọ.

Timi Yakubu, alakoso eto iṣuna; Ọmọwe Garba Abdul S. U., akọwe agba nileeṣẹ to n ri sọrọ oṣiṣẹ lori ṣoju ijọba apapọ; nigba ti aarẹ ẹgbẹ NLC, Joe Ajaero ati akọwe agba fun ajọ JNPSNC, Olowoyo Gbenga, wa nibi ipade adehun tuntun naa pẹlu.

Kí ni wọ́n fẹnukò lé lórí?

Nibi ipade naa, ijọba apapọ yoo bẹrẹ sii san ẹgbẹrun lọna aadọrin naira fun gbogbo oṣiṣẹ patapata fun oṣu mẹfa gbako, ati pe inu oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni yoo bẹrẹ.

Ijọba tun buwọ lu owo ajẹmọnu, eyi to bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Karun-un, ọdun 2026, nigba ti owo ajẹẹlẹ yoo bẹrẹ ni sisan lati ibẹrẹ oṣu Kọkanla, ati pe oṣu mẹta-mẹta ni ijọba yoo maa san an.

Ni afikun, ijọba sọ pe ohun yoo san owo ajẹmọnu oṣu mọkandinlogun fun awọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera, eyi ti wọn yoo san fun oṣu mẹyta gbako, bẹrẹ lati oṣu Kejila, ọdun 2026.

Lori afikun owo oṣu tuntun, ijọba apapọ sọ pe wọn yoo ṣagbekalẹ igbimọ to n ri si ijiroro owo oṣu, ti wọn yoo si bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ.

Kókó pàtàkí márùn-ún tó wà nínú àdéhùn náà

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Atẹjade wọn buwọlu lẹyin ipade, ni wọn ti koko marun-un ti wọn fẹnu rẹ ko le lori, awọn si ni:

Owo Oṣu Tuntun:

A fẹnuko pe wọn yoo gbe igbimọ ti yoo ri sọrọ owo oṣu tuntun kalẹ, ti wọn yoo si bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ. Sibẹ, a ko fẹnuko lori ṣiṣe agbekalẹ owo oṣu tuntun ati igba ti sisan rẹ yoo bẹrẹ.

Adinku lori owo epo rọbii:

Ijọba apapọ yoo san owo iranwọ ẹgbẹrun lọna aadọrin naira kaakiri ẹka iṣẹ ijọba fun oṣu mẹfa, ti yoo si bẹrẹ inu oṣu Kọkanla, ọdun 2026.

Ijọba apapọ ti buwọ lu awọn owo gba ma binu fun awọn oṣiṣẹ, ti sisan rẹ si ti bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Karun-un, ọdun 2026. Sisan owo oṣu ajẹẹlẹ yoo bẹrẹ ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni oṣu mẹta-mẹta.

Owo oṣu asaalẹ fun oṣu mọkandinlogun fawọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera ni yoo di sisan laarin oṣu mẹta, bẹrẹ lati oṣu Kejila, ọdun 2026.

Idẹrun owo ori sisan fawọn oṣiṣẹ

Gẹgẹ bi owo ori sisan ṣe ṣe pataki, ọrọ adinku ninu owo ori sisan fawọn oṣiṣẹ la o gbe lọ siwaju igbimọ iṣakoso, iyẹn NEC.

Owo ijamba fun awọn agbẹ:

Ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹ agbẹ ati aabo lori ounjẹ ti fi orukọ awọn ti yoo jẹ anfaani ati iye owo to jẹ naa ranṣẹ si ileeṣẹ to n ri sọrọ owo oṣu sisan, NSIWC lati ṣa ayẹwo rẹ. Ayẹwo naa ni yoo pari laaarin ọsẹ meji, ko to di pe wọn buwọlu fun sisan.

Ayipada rampẹ ni CONHESS

Ileeṣẹ NSIWC ti ṣeleri lati pari gbogbo agbeyẹwo lori idagbasoke naa laaarin ọsẹ mẹta pere, lati le jẹ ki igbimọ aarẹ lori owo oṣu gbe ipinnu kalẹ lori ayipada CONHESS.

Nibi ipade naa, wọn rọ awọn ijọba ipinlẹ ati ibilẹ lati ṣiṣẹ lori agbekalẹ ijọba apapọ yii, bẹẹ ni wọn rọ awọn ẹgbẹ kaakiri lati dide sọrọ fifi idi rẹ mulẹ kaakiri ẹka iṣẹ ijọba.

Awọn alakoso naa ni wọn tun sọ pe wọn yoo jokoo ipade tuntun pada lẹyin oṣu kan, lati wo bi nnkan yoo ṣe lọ laaarin asiko naa.