Buhari: Mo gbọdọ̀ lọ́ra kàwé, kí ń tó buwọ́ lùú

Aarẹ Muhammadu
Àkọlé àwòrán, lBuhari ní òun lọ́ra láti buwọ́ lu ìwe kankan nítorí èèyàn kìí kánjú lá ọbẹ̀ gbóná.
Published

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti gbá àwọn èèyàn tó ń pèé ní bàbá go slow pe òun ń lọ́ra láti buwọ́ lu ìwe kankan nítorí èèyàn kìí kánjú lá ọbẹ̀ gbóná.

Buhari ní òun kò tètè fọwọ́sí ìwé àdéhùn lóríi ètò ìdókówó ọ̀fẹ́ jádè-jádò àgbáyé, nítorí pé òun lọ́ra láti kàwé.

Buhari kéde ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń gbàlejò ààrẹ orílẹ̀-èdè South Africa, Cyril Ramaphosa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Okunrounmu: Ijọba Buhari jẹ ijiya Ọlọrun fun Naijiria

"A gbọ́dọ̀ sọra nípa bíbu ọwọ́ lu àwọn ìwé àdéhùn tí yóò bá figa-gbága pẹ̀lú ètò ìgbani-sísẹ àti kárà-kárà ọjà ní orílẹ̀-èdè yìí, tó sì tún leè se àkóbá fún àseyọrí àwọn iléesẹ̀ ńlá-ńlá gbogbo nílẹ̀ yìí."

"Mo lọ́ra láti kàwé, bóyá nítorí pé mo jẹ́ ajagun-fẹ̀yìntì ni. Èmi kìí tètè kàwé lásìkò, màá sì kàá dáa-dáa kí ń tó buwọ́ lùú."