Ayajọ iranti awọn akọni: Ayẹyẹ waye kaakiri orilẹede Naijiria

Nipinlẹ Eko, igbakeji Gomina se ayẹyẹ ọjọ naa
Àkọlé àwòrán, Nipinlẹ Eko, igbakeji Gomina se ayẹyẹ ọjọ naa
Published

Lọjọ aje tii se ọjọ kẹẹdogun osu kini ọdun 2018 ni ayajọ ọjọ iranti awọn ologun to subu loju ija waye kaakiri tibu-toro ilẹ Naijiria.

Awọn ologun bu ọla fun awọn to ti lọ saaju wọn
Àkọlé àwòrán, Awọn ologun bu ọla fun awọn to ti lọ saaju wọn

Ni ẹkun iwọ oorun guusu awọn ipinlẹ bii Ondo, Ọyọ, Ọsun, Ekiti pẹlu ko gbẹyin ninu sise ayajọ naa.

Gomina Arẹgbẹsọla siwaju ayẹyẹ yii nilu Osogbo
Àkọlé àwòrán, Gomina Arẹgbẹsọla siwaju ayẹyẹ yii nilu Osogbo

Ni ipinlẹ Ọsun, Gomina Arẹgbẹsọla to saaju tito ododo soju ẹyẹ awọn akọni ni akoko to latubọ yanana isọkan ati aabo lorilẹede Naijiria.

Ipe fun isọkan ati abo waye lasiko ayẹyẹ ayajọ awọn akọni lorilẹede Naijiria.
Àkọlé àwòrán, Ipe fun isọkan ati abo waye lasiko ayẹyẹ ayajọ awọn akọni lorilẹede Naijiria.

Gomina ana nipinlẹ naa, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla pe fun atunyẹwo ilana isẹ awọn abọde ologun ti wọn fara jiya loju ija fun isọkan ilẹ Naijiria.

Gomina Akeredolu lo lewaju ayajọ naa ni ilu Akurẹ
Àkọlé àwòrán, Gomina Akeredolu lo lewaju ayajọ naa ni ilu Akurẹ

Ni ipinlẹ Ondo, gomina Rotimi Akeredolu ke si awọn agbofinro gbogbo lorilẹede Naijiria lati tubọ ji giri si ipenija ti gulegule wahala awọn darandaran nko ba eto abo.

Gomina Akeredolu sọrọ lori gulegule awọn darandaran
Àkọlé àwòrán, Gomina Akeredolu sọrọ lori gulegule awọn darandaran

Ni ipinlẹ Ọyọ, Gomina Ajimọbi dupẹ pupọ lọwọ awọn oloogun ilẹ Naijiria fun diduro sinsin fun isọkan ati alaafia araalu.

Akoko ayajọ awọn akọni jẹ akoko imọriri awọn ologun
Àkọlé àwòrán, Akoko ayajọ awọn akọni jẹ akoko imọriri awọn ologun