Ibarapa mejeeje: Wo àwọn ibùdó ìtàn Mánigbàgbé ni Eruwa, Tapa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Published

Ọgbẹni Olugbenga Omotayo tó jé agbatẹru irinajo afẹ́ naa kaakiri Ibarapa mejeeje salaye lori irinajo naa fún BBC.

oke
Àkọlé àwòrán, Oke agbeleka Aroye ree ni Idere. Oke ti itan ni o ni idi ti o fi gbe awọn oke miran ru doke ti wọn fi jọ n wo sanmọ
Okuta
Àkọlé àwòrán, Okuta nla to da duro lagbede meji oke nla ni Itabo-Lanlate. Ilẹ Ibarapa jẹ ọkan lara ẹkun marun un to wa ni ipinlẹ Oyo ni Guusu Naijiria.
odo
Àkọlé àwòrán, Igboora, Igangan, Tapa, Ayete, Idere, Eruwa ati Lanlate ni Ibarapa Meje ti ikọ Tourism agenda ṣabẹwo irinajo afẹ si. Adagun odo yii wa ni Oke Idere nilu Idere
oke
Àkọlé àwòrán, Oke Imofin ree ni ilu Tapa to jẹ ọkan lara ibudo Manigbagbe ni Ibarapa ni ipinlẹ Oyo
ibudo
Àkọlé àwòrán, Awọn ibudo wọnyii jẹ eyi to ni itan to rọ mọ wọn ati igbagbọ awọn iran Yoruba nipa wọn
apa
Àkọlé àwòrán, Igba ni nọmba awọn oju apa yii nigba ti wọn kaa ni Eruwa.
oke
Àkọlé àwòrán, Ogbeni Olugbenga ati Kọmiṣọnna fun ọdọ ati ere idaraya ni ipinlẹ Oyo, Seun Fakorede naa kọwọ jọ rin irin ajo afẹ naa ni Ibarapa ni.
oke
Àkọlé àwòrán, Diẹ lara awọn akọni to to ẹgbẹrun kan abọ to jade lati rin irin ajo afẹ naa kaakiri Ibarapa mejeeje lasiko yii
oke
Àkọlé àwòrán, Ori oke Akolu ni ilu Eruwa ti Ọba ko gbọdọ ṣiju woo mọ ni kete to ba ti gba ade. Oke yii de fila nla lori rẹ tente, itan manigbagbe pọ to rọ mọ eewọ yii to le ja si iku fun ori ade, nibẹ ni ojubọ nla tun wa.
oke
Àkọlé àwòrán, Adun irinajo afẹ ni ki o le rin nibi ti awọn akọni ti rin kọja ri bii igba iho ilẹ ti awọn arinrinajo ki ẹsẹ bọ yii ni Onigbaparo
odo
Àkọlé àwòrán, Olorogun ree ni Idere. Igbagbọ awọn eniyan ni pe alagbara obinrin kan lo parada di asdagun yii laye atijọ. Adagun yii ni wọn gba pe ko ni ọgbun
oke
Àkọlé àwòrán, Odo ẹlẹja ree lori oke ni Ibarapa mejeeje ni ẹkun kan ninu marun un to wa ni ipinlẹ Oyo ni Guusu Naijiria
odo
Àkọlé àwòrán, Adagun odo ti ẹnikẹni ko le bu wẹ nibẹ ti ọpọ itan rọ mọ iṣẹda rẹ
arinrinajo
Àkọlé àwòrán, Eyi wa lẹ ni ko si nkan, pẹlu ayọ ati idunnu ni awọn olukopa ninu eto irinajo afẹ naa fi pari rẹ ni Ibarapa mejeeje ni ipinlẹ Oyo