Sudan protest in pictures: Bó ṣe ń lọ lórílẹ̀èdè Sudan

Published

Wọ̀nyìí ni àwọn àwòrán tó fakọyọ ju láti orílẹ̀èdè Sudan lọ̀sẹ̀ yìí.

Awọn ara Sudan
Àkọlé àwòrán, KHARTOUM, SUDAN - APRIL 13: Awọn eniyan korajọ lati ṣe ajọyọ niwaju olu ile iṣẹ awọn ologun lẹyin ti Minisita ọ̀rọ̀ abo, Ahmed Awad Ibn Auf kede pe oun fipo silẹ gẹg bi olori ẹgbẹ ọmọ ogun to boju to gbigbe ijọba le ẹlomiiran lọ́wọ́ ni Khatourm, Sudan. Aarẹ Sudan, Omar Al-Bashir ni awọn ologun Sudan le kuro lori alefa lẹyin iwọde ifẹhonu han fun ọpọlọpọ oṣu to waye lodi si iṣejọba rẹ fun ọgbọ̀n ọdun.
Mínísítà ètò àbò lórílẹ̀èdè Sudan, Awad Ibn Auf
Àkọlé àwòrán, Mínísítà ètò àbò lórílẹ̀èdè Sudan, Awad Ibn Auf tó fipò sílẹ̀ lẹ́yìn tó dárí ìgbésẹ̀ tó yọ ààrẹ Omar Al-Bashir nipo.
Awọn ara Sudane
Àkọlé àwòrán, Awọn obinrin Sudan forin sẹnu plu bi wọn ṣe tu yaaya si igboro fun ajọyọ
Awọn ara Sudan
Àkọlé àwòrán, KHARTOUM, SUDAN - APRIL 13: Awọn eniyan korajọ lati ṣe ajọyọ niwaju olu ile iṣẹ awọn ologun lẹyin ti Minisita ọ̀rọ̀ abo, Ahmed Awad Ibn Auf kede pe oun fipo silẹ gẹg bi olori ẹgbẹ ọmọ ogun to boju to gbigbe ijọba le ẹlomiiran lọ́wọ́ ni Khatourm, Sudan.
Awọn ara orilẹede Sudan
Àkọlé àwòrán, Awọn ara orilẹede Sudan pe jọ niwaju olu ile iṣẹ awọn ologun lẹyin ti Minisita ọ̀rọ̀ abo, Ahmed Awad Ibn Auf kede pe oun fipo silẹ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ ọmọ ogun to boju to gbigbe ijọba le ẹlomiiran lọ́wọ́ ni Khatourm, Sudan fun ajọyọ.
asia orilẹede Sudan
Àkọlé àwòrán, Arakunrin kan n ju asia orilẹede Sudan lati oju ferese ọkọ rẹ bi awọn mii naa ṣe tu sigboro lati ba awọn ara wọn to ku ṣe ajọyọ. Ajọyọ yii b silẹ nigba ti olori ẹgbẹ ọmọ ogun to boju to gbigbe ijọba le ẹlomiiran lọ́wọ́ lẹyin ọjọ kan pere ti wọn bura wọle fun un.
Sudan
Àkọlé àwòrán, Ọmọdebinrin kan lati Sudan naa n ju asia kekere rẹ bi awọn eniyan ṣe tu si igboro fun ajọyọ ni Khatourm, olu ilu orilẹede Sudan.
Awọn ara Sudan
Àkọlé àwòrán, Sufi whirling dervish at Omdurman sheikh Hamad el Nil tomb, Khartoum State, Omdurman, Sudan on January 4, 2019 in Omdurman, Sudan.
Sudan
Àkọlé àwòrán, Awọn ara Sudan atawọn ologun gbe ọwọ ami iṣẹgun wọn, V for Victory. Ọgọọrọ awọn to n ṣe ajọyọ lo kun ojude ilu. bi awọn kan ṣe n di mọ 'ra wọn gbagi lawọn kan n fẹ aisa wọn soke.
Sudan
Àkọlé àwòrán, Ọmọ Sudan kan n ju asia orilẹede Sundan. Lori asia yii ni arakunrin yii kọ ọ̀pọlọpọ̀ ọ̀rọ̀ sori rẹ.
Awọn ologun
Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ikọ ogun alaabo n ṣe ajọyọ pẹlu asia ati ami V for Victory.
Awọn ara Sudan
Àkọlé àwòrán, Awọn ara Sudan fọn si igboro ni olu ilu Sudan, Khatourm.
Awọn ara Sudan
Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọde n jo, wọn fo fáyọ̀.